-
Àwọn Onídàájọ́ 7:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Gídíónì ránṣẹ́ sí gbogbo agbègbè olókè Éfúrémù pé: “Ẹ lọ gbógun ja Mídíánì, kí ẹ sì gba ọ̀nà tó dé ibi omi mọ́ wọn lọ́wọ́ títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì.” Gbogbo àwọn ọkùnrin Éfúrémù wá kóra jọ, wọ́n sì gba ibi omi náà títí dé Bẹti-bárà àti Jọ́dánì.
-