-
Àwọn Onídàájọ́ 9:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Ṣé òótọ́ inú lẹ wá fi hùwà yìí, ṣé ohun tó tọ́ lẹ sì ṣe bí ẹ ṣe fi Ábímélékì jọba,+ ṣé ìwà rere lẹ hù sí Jerubáálì àti agbo ilé rẹ̀, ṣé ohun tó sì yẹ ẹ́ lẹ ṣe fún un? 17 Nígbà tí bàbá mi jà fún yín,+ ó fi ẹ̀mí* ara rẹ wewu, kó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ Mídíánì.+ 18 Àmọ́ lónìí, ẹ ti dìde sí agbo ilé bàbá mi, ẹ sì pa àwọn ọmọ rẹ̀, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan.+ Ẹ wá fi Ábímélékì, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀,+ jọba lórí àwọn olórí Ṣékémù, torí pé arákùnrin yín ni.
-