11 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tó dira ogun látinú ìdílé àwọn ọmọ Dánì wá gbéra láti Sórà àti Éṣítáólì.+ 12 Wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Kiriati-jéárímù+ ní Júdà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibi tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Kiriati-jéárímù yẹn ní Mahane-dánì+ títí dòní.