-
Àwọn Onídàájọ́ 14:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń pa dà lọ kó lè mú obìnrin náà wá sílé,+ ó yà wo òkú kìnnìún náà, ó sì rí oyin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò oyin nínú òkú kìnnìún náà. 9 Ó wá fá oyin náà sọ́wọ́, ó sì ń lá a bó ṣe ń rìn lọ. Nígbà tó pa dà lọ bá bàbá àti ìyá rẹ̀, ó fún wọn jẹ lára rẹ̀. Àmọ́ kò sọ fún wọn pé inú òkú kìnnìún ni òun ti fá oyin náà.
-