5 Àwọn alákòóso Filísínì wá lọ bá obìnrin náà, wọ́n sì sọ pé: “Tàn án,+ kí o lè mọ ohun tó mú kó lágbára tó báyìí àti bí a ṣe lè kápá rẹ̀, ká dè é, ká sì borí rẹ̀. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa fún ọ ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà.”