22 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n fara pa mọ́+ sí agbègbè olókè Éfúrémù gbọ́ pé àwọn Filísínì ti fẹsẹ̀ fẹ, ni àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í lépa wọn lọ lójú ogun náà. 23 Torí náà, Jèhófà gba Ísírẹ́lì là lọ́jọ́ yẹn,+ ogun náà sì lọ títí dé Bẹti-áfénì.+
51 Dáfídì sáré lọ, ó sì dúró ti Filísínì náà. Ó gbá idà Filísínì+ náà mú, ó fà á yọ nínú àkọ̀ rẹ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀ kúrò kó lè rí i dájú pé ó ti kú. Nígbà tí àwọn Filísínì rí i pé alágbára wọn ti kú, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ.+