-
1 Sámúẹ́lì 9:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Gbàrà tí ẹ bá ti wọ ìlú náà, ẹ máa rí i kó tó gòkè lọ sí ibi gíga láti jẹun. Àwọn èèyàn náà kò ní jẹun títí á fi dé, nítorí òun ló máa gbàdúrà* sí ẹbọ náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn tí a pè tó lè jẹun. Torí náà, ẹ tètè gòkè lọ, ẹ máa rí i.”
-
-
1 Sámúẹ́lì 9:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ni alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ẹran àti àwọn ohun tó wà lórí rẹ̀ síwájú Sọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì sì sọ pé: “Ohun tí a tọ́jú dè ọ́ ló wà níwájú rẹ yìí. Jẹ ẹ́, nítorí àkókò pàtàkì yìí ni wọ́n ṣe tọ́jú rẹ̀ dè ọ́. Mo ti sọ fún wọn pé, ‘mò ń retí àwọn àlejò.’” Torí náà, Sọ́ọ̀lù bá Sámúẹ́lì jẹun ní ọjọ́ yẹn.
-