11 Kèké mú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, ilẹ̀ tí wọ́n sì fi kèké pín fún wọn wà láàárín àwọn èèyàn Júdà+ àtàwọn èèyàn Jósẹ́fù.+ 12 Ní apá àríwá, ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì, ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò+ ní àríwá, ó dé orí òkè lápá ìwọ̀ oòrùn, ó sì lọ títí dé aginjù Bẹti-áfénì.+