17 O ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tí a máa pa run,*+ kí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi lè rọ̀, kó lè ṣàánú rẹ, kó yọ́nú sí ọ, kó sì mú kí o pọ̀, bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá rẹ gẹ́lẹ́.+
9 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí* àti agbo ẹran tó dára jù, títí kan ọ̀wọ́ ẹran, àwọn ẹran àbọ́sanra, àwọn àgbò àti gbogbo ohun tó dára.+ Wọn ò fẹ́ pa wọ́n run. Àmọ́ wọ́n pa gbogbo nǹkan tí kò ní láárí, tí kò sì wúlò run.