12 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e ni Élíásárì+ ọmọ Dódò ọmọ Áhóhì.+ Ó wà lára àwọn jagunjagun mẹ́ta tó lákíkanjú. 13 Ó wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pasi-dámímù,+ níbi tí àwọn Filísínì kóra jọ sí láti jagun. Lákòókò náà, ilẹ̀ kan wà tí ọkà bálì pọ̀ sí, àwọn èèyàn sì ti sá lọ nítorí àwọn Filísínì.