13 Torí náà, Sámúẹ́lì mú ìwo tí òróró wà nínú rẹ̀,+ ó sì fòróró yàn án lójú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún Dáfídì lágbára láti ọjọ́ náà lọ.+ Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì gba Rámà lọ.+
37 Dáfídì wá fi kún un pé: “Jèhófà tó gbà mí lọ́wọ́* kìnnìún àti bíárì náà, ló máa gbà mí lọ́wọ́ Filísínì yìí.”+ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”