-
1 Sámúẹ́lì 20:19-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tó bá fi máa di ọjọ́ kẹta, àárò rẹ á ti máa sọ wá gan-an, kí o wá sí ibi tí o fara pa mọ́ sí lọ́jọ́sí,* kí o sì dúró sí tòsí òkúta tó wà níbí yìí. 20 Màá wá ta ọfà mẹ́ta sí apá ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bíi pé nǹkan kan wà tí mo fẹ́ ta ọfà sí. 21 Nígbà tí mo bá rán ìránṣẹ́ mi, màá sọ fún un pé, ‘Lọ wá àwọn ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún ìránṣẹ́ náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà nìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, kó wọn,’ nígbà náà, bí Jèhófà ti wà láàyè, o lè pa dà wá torí pé ó túmọ̀ sí àlàáfíà fún ọ, kò sì séwu. 22 Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọkùnrin náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà ṣì wà níwájú,’ nígbà náà, kí o máa lọ, nítorí pé Jèhófà fẹ́ kí o lọ.
-