10 Mo tún ń fi Rúùtù ará Móábù, ìyàwó Málónì, ṣe aya kí n lè dá orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà pa dà sórí ogún rẹ̀,+ kí orúkọ ọkùnrin tó ti kú náà má bàa pa rẹ́ ní ìdílé rẹ̀, kó má sì pa rẹ́ ní ẹnubodè ìlú. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi lónìí.”+
17 Ìgbà náà ni àwọn obìnrin tó wà ládùúgbò fún ọmọ náà ní orúkọ. Wọ́n sọ pé, “Náómì ti ní ọmọkùnrin kan.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì.+ Òun ló wá bí Jésè,+ bàbá Dáfídì.
47 Sọ́ọ̀lù fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá rẹ̀ jà níbi gbogbo, ó bá àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ jà, ó tún bá àwọn ọmọ Édómù+ àti àwọn ọba Sóbà+ pẹ̀lú àwọn Filísínì+ jà; ó sì ń ṣẹ́gun níbikíbi tó bá lọ.