-
1 Sámúẹ́lì 11:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ni wọ́n bá sọ fún àwọn òjíṣẹ́ tó wá pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún àwọn èèyàn Jábéṣì ní Gílíádì nìyí, ‘Lọ́la, nígbà tí oòrùn bá mú, a máa gbà yín.’” Àwọn òjíṣẹ́ náà wá lọ sọ fún àwọn ọkùnrin Jábéṣì, inú wọn sì dùn gan-an. 10 Torí náà, àwọn ọkùnrin Jábéṣì sọ fún àwọn ọmọ Ámónì pé: “Lọ́la, a máa fi ara wa lé yín lọ́wọ́, kí ẹ ṣe ohun tó bá wù yín sí wa.”+
11 Ní ọjọ́ kejì, Sọ́ọ̀lù pín àwọn èèyàn náà sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n lọ sí àárín ibùdó náà ní àkókò ìṣọ́ òwúrọ̀,* wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ Ámónì+ títí ọ̀sán fi pọ́n. Àwọn tó yè bọ́ fọ́n ká, tó fi jẹ́ pé kò sí méjì lára wọn tí ó wà pa pọ̀.
-