-
1 Kíróníkà 13:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí náà, ẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ ba Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ pé: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi ló yẹ kí n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá?”+ 13 Dáfídì kò gbé Àpótí náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì, àmọ́ ó ní kí wọ́n gbé e lọ sí ilé Obedi-édómù ará Gátì. 14 Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sì wà ní agbo ilé Obedi-édómù, oṣù mẹ́ta ló fi wà ní ilé rẹ̀, Jèhófà sì ń bù kún agbo ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun tó ní.+
-