-
1 Kíróníkà 16:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Torí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wọlé, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ nínú àgọ́ tí Dáfídì pa fún un;+ wọ́n mú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́.+ 2 Nígbà tí Dáfídì parí rírú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ náà, ó fi orúkọ Jèhófà súre fún àwọn èèyàn náà. 3 Láfikún sí i, ó pín ìṣù búrẹ́dì ribiti àti ìṣù èso déètì àti ìṣù àjàrà gbígbẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fún kálukú wọn lọ́kùnrin lóbìnrin.
-