ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 49:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+

  • 1 Sámúẹ́lì 15:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ìgbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Mo ti ṣẹ̀, torí mo ti tẹ àṣẹ Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ lójú, nítorí mo bẹ̀rù àwọn èèyàn, mo sì fetí sí ohun tí wọ́n sọ.

  • 1 Sámúẹ́lì 15:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Sámúẹ́lì wá sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, yóò sì fún ọmọnìkejì rẹ tó sàn jù ọ́ lọ.+

  • 1 Sámúẹ́lì 16:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Torí náà, Sámúẹ́lì mú ìwo tí òróró wà nínú rẹ̀,+ ó sì fòróró yàn án lójú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún Dáfídì lágbára láti ọjọ́ náà lọ.+ Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì gba Rámà lọ.+

  • 2 Sámúẹ́lì 5:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Dáfídì nígbà tí ó di ọba, ogójì (40) ọdún+ ló sì fi ṣàkóso. 5 Ọdún méje àti oṣù mẹ́fà ló fi jọba lórí Júdà ní Hébúrónì, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ní Jerúsálẹ́mù.+

  • 1 Kíróníkà 11:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú ní Hébúrónì níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Sámúẹ́lì sọ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́