3 Nígbà tí Dáfídì dé ilé rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,+ ọba mú àwọn wáhàrì mẹ́wàá tó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ilé,+ ó sì fi wọ́n sínú ilé tó ní ẹ̀ṣọ́. Ó ń fún wọn ní oúnjẹ àmọ́ kò bá wọn lò pọ̀.+ Inú àhámọ́ ni wọ́n wà títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n ń gbé bíi pé opó ni wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ wọn ṣì wà láàyè.