-
1 Sámúẹ́lì 17:50Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
50 Bí Dáfídì ṣe fi kànnàkànnà àti òkúta kan ṣẹ́gun Filísínì náà nìyẹn; ó mú Filísínì náà balẹ̀, ó sì pa á, bó tilẹ̀ jẹ́ pe kò sí idà lọ́wọ́ Dáfídì.+
-
-
1 Sámúẹ́lì 19:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nígbà tó yá, ogun tún bẹ́ sílẹ̀, Dáfídì sì jáde lọ bá àwọn Filísínì jà, ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, wọ́n sì sá kúrò níwájú rẹ̀.
-
-
2 Sámúẹ́lì 10:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àmọ́, àwọn ará Síríà sá kúrò níwájú Ísírẹ́lì; Dáfídì sì pa ọgọ́rùn-ún méje (700) àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) àwọn agẹṣin ará Síríà, ó ṣá Ṣóbákì olórí àwọn ọmọ ogun wọn balẹ̀, ó sì kú síbẹ̀.+
-