5 “Ìwọ náà mọ ohun tí Jóábù ọmọ Seruáyà ṣe sí mi dáadáa, ohun tó ṣe sí àwọn olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì méjì, ìyẹn Ábínérì+ ọmọ Nérì àti Ámásà+ ọmọ Jétà. Ó pa wọ́n nígbà tí kì í ṣe pé ogun ń jà, ó mú kí ẹ̀jẹ̀+ ogun ta sára àmùrè tó sán mọ́ ìbàdí rẹ̀ àti sára bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.