-
1 Kíróníkà 11:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e ni Élíásárì+ ọmọ Dódò ọmọ Áhóhì.+ Ó wà lára àwọn jagunjagun mẹ́ta tó lákíkanjú. 13 Ó wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pasi-dámímù,+ níbi tí àwọn Filísínì kóra jọ sí láti jagun. Lákòókò náà, ilẹ̀ kan wà tí ọkà bálì pọ̀ sí, àwọn èèyàn sì ti sá lọ nítorí àwọn Filísínì. 14 Àmọ́ ó dúró ní àárín ilẹ̀ náà, kò jẹ́ kí wọ́n gbà á, ó sì ń pa àwọn Filísínì náà, tó fi jẹ́ pé Jèhófà mú kí ìṣẹ́gun*+ ńlá wáyé.
-