6 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún Áhímélékì ọmọ Hétì+ àti Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà,+ ẹ̀gbọ́n Jóábù pé: “Ta ló máa tẹ̀ lé mi lọ sí ibùdó lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù?” Ábíṣáì fèsì pé: “Màá tẹ̀ lé ọ.”
17 Ní kíá, Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà wá ràn án lọ́wọ́,+ ó ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì pa á. Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Dáfídì búra fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ bá wa lọ sójú ogun mọ́!+ Má ṣe jẹ́ kí iná Ísírẹ́lì kú!”+