-
2 Kíróníkà 3:10-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Lẹ́yìn náà, ó ṣe ère kérúbù méjì sínú apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+ 11 Gígùn ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà lápapọ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; ìyẹ́ apá kan kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ìyẹ́ apá kérúbù kejì. 12 Ìyẹ́ apá kan kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri kejì ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ọ̀kan lára ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. 13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù yìí nà jáde ní ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí inú.*
-
-
2 Kíróníkà 5:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde sórí ibi tí Àpótí náà wà, tó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà bo Àpótí náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ láti òkè.
-