-
1 Kíróníkà 15:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àfi àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ni Jèhófà yàn láti máa gbé Àpótí Jèhófà àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun nígbà gbogbo.”+
-
-
1 Kíróníkà 15:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ọ̀pá+ gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ lé èjìká wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa látọ̀dọ̀ Jèhófà.
-
-
2 Kíróníkà 5:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nítorí náà, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, àwọn ọmọ Léfì sì gbé Àpótí náà.+ 5 Wọ́n gbé Àpótí náà àti àgọ́ ìpàdé + wá pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò mímọ́ tó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì* ló gbé wọn wá. 6 Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn tó ní kí wọ́n pàdé òun, wà níwájú Àpótí náà. Àgùntàn àti màlúù tí wọ́n fi rúbọ+ pọ̀ débi pé wọn ò ṣeé kà, wọn ò sì níye.
-