-
Nehemáyà 2:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Lẹ́yìn náà, mo sọ fún ọba pé: “Tó bá dáa lójú ọba, jẹ́ kí wọ́n fún mi ní àwọn lẹ́tà tí màá fún àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò,*+ kí wọ́n lè jẹ́ kí n kọjá títí màá fi dé Júdà 8 àti lẹ́tà tí màá fún Ásáfù tó ń ṣọ́ Ọgbà Ọba,* kó lè fún mi ní gẹdú tí màá fi ṣe òpó àwọn ẹnubodè Odi+ Ilé Ọlọ́run* àti ògiri ìlú náà+ pẹ̀lú ilé tí màá gbé.” Nítorí náà, ọba kó wọn fún mi,+ torí pé ọwọ́ rere Ọlọ́run mi wà lára mi.+
-