15 Ọba Sólómọ́nì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe igba (200) apata ńlá,+ (ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ṣékélì àyọ́pọ̀ wúrà ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn),+ 16 ó sì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) asà (wúrà mínà mẹ́ta ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú Ilé Igbó Lẹ́bánónì.+