ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 34:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+

  • Diutarónómì 7:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dána rárá.* O ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún àwọn ọmọkùnrin wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ.+

  • Jóṣúà 23:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Àmọ́ tí ẹ bá yí pa dà pẹ́nrẹ́n, tí ẹ sì rọ̀ mọ́ ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n ṣẹ́ kù+ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá wọn dána,*+ tí ẹ sì ń bára yín ṣọ̀rẹ́, 13 kí ẹ mọ̀ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run yín kò ní bá yín lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò* mọ́.+ Wọ́n máa di pańpẹ́ àti ìdẹkùn fún yín, wọ́n máa di pàṣán ní ẹ̀gbẹ́ yín+ àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ fi máa pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.

  • 2 Kọ́ríńtì 6:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú* àwọn aláìgbàgbọ́.+ Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà tí kò bófin mu ní?+ Tàbí kí ló pa ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn pọ̀?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́