16 Ní ti gbogbo Ísírẹ́lì, torí pé ọba ò gbọ́ tiwọn, àwọn èèyàn náà fún ọba lésì pé: “Kí ló pa àwa àti Dáfídì pọ̀? A ò ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè. Ìwọ Ísírẹ́lì, kí kálukú lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ̀. Ìwọ Dáfídì,+ máa mójú tó ilé ara rẹ!” Bí gbogbo Ísírẹ́lì ṣe pa dà sí ilé wọn nìyẹn.+