-
2 Àwọn Ọba 23:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ó tún wó pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn ibi gíga tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì kọ́, tó mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Lẹ́yìn tó wó pẹpẹ yẹn àti ibi gíga náà, ó dáná sun ibi gíga náà, ó lọ̀ ọ́ kúnná, ó sì sun òpó òrìṣà*+ náà.
16 Nígbà tí Jòsáyà yíjú pa dà, tó sì rí àwọn sàréè tó wà lórí òkè, ó ní kí wọ́n kó àwọn egungun kúrò nínú àwọn sàréè náà, kí wọ́n sì sun wọ́n lórí pẹpẹ náà, kí ó lè sọ ọ́ di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kéde, nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀.+
-