4 Láfikún sí i, wọ́n wó pẹpẹ àwọn Báálì lulẹ̀ níṣojú rẹ̀, ó sì gé àwọn pẹpẹ tùràrí tó wà lókè orí wọn lulẹ̀. Ó tún fọ́ àwọn òpó òrìṣà àti àwọn ère gbígbẹ́ pẹ̀lú àwọn ère onírin sí wẹ́wẹ́, ó lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú, ó sì wọ́n ekuru wọn sórí sàréè àwọn tó ń rúbọ sí wọn tẹ́lẹ̀.+