-
1 Àwọn Ọba 14:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Nítorí ohun tí o ṣe yìí, màá mú àjálù bá ilé Jèróbóámù, màá pa gbogbo ọkùnrin* ilé Jèróbóámù rẹ́,* títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì, màá sì gbá ilé Jèróbóámù+ dà nù, bí ìgbà tí èèyàn gbá ìgbẹ́ ẹran kúrò láìku nǹkan kan! 11 Èèyàn Jèróbóámù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni ajá yóò jẹ; èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ, nítorí Jèhófà ti sọ ọ́.”’
-
-
1 Àwọn Ọba 15:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Gbàrà tí ó di ọba, ó ṣá gbogbo ilé Jèróbóámù balẹ̀. Kò ṣẹ́ alààyè kankan kù lára àwọn ará ilé Jèróbóámù; ó ní kí wọ́n pa wọ́n rẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Áhíjà ọmọ Ṣílò,+ sọ.
-