25 Bí àpẹẹrẹ, mò ń sọ fún yín ní tòótọ́ pé: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ opó ló wà ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Èlíjà, nígbà tí a sé ọ̀run pa fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà, tí ìyàn sì mú gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ náà.+ 26 Síbẹ̀, a kò rán Èlíjà sí ìkankan nínú àwọn obìnrin yẹn, àfi opó tó wà ní Sáréfátì nílẹ̀ Sídónì nìkan.+