2 Ọlọ́run ò kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tó kọ́kọ́ mọ̀.+ Ṣé ẹ ò mọ ohun tí ìwé mímọ́ sọ nípa Èlíjà ni, bí ó ṣe ń fi ẹjọ́ Ísírẹ́lì sùn nígbà tó ń bẹ Ọlọ́run? 3 “Jèhófà, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọ́n ti hú àwọn pẹpẹ rẹ kúrò, èmi nìkan ló ṣẹ́ kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí mi.”+