-
2 Àwọn Ọba 2:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ó gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọkùnrin kan jáde wá láti inú ìlú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń sọ fún un pé: “Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!” 24 Níkẹyìn, ó bojú wẹ̀yìn, ó wò wọ́n, ó sì gégùn-ún fún wọn ní orúkọ Jèhófà. Ni abo bíárì+ méjì bá jáde láti inú igbó, wọ́n sì fa méjìlélógójì (42) lára àwọn ọmọ náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+
-