52 Wọ́n máa dó tì ọ́, wọ́n máa sé ọ mọ́ inú gbogbo ìlú* rẹ, jákèjádò ilẹ̀ rẹ títí àwọn ògiri rẹ tó ga, tí o fi ṣe odi tí o gbẹ́kẹ̀ lé fi máa wó lulẹ̀. Àní ó dájú pé wọ́n máa dó tì ọ́ nínú gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ.+
20Nígbà náà, Bẹni-hádádì+ ọba Síríà+ kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn; ó jáde lọ, ó dó ti+ Samáríà,+ ó sì gbéjà kò ó.