-
1 Sámúẹ́lì 9:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ìránṣẹ́ náà tún dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Wò ó! Ìdá mẹ́rin ṣékélì* fàdákà wà lọ́wọ́ mi. Màá fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, yóò sì sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.”
-
-
1 Àwọn Ọba 14:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí náà, Jèróbóámù sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, dìde, yí ìmúra rẹ pa dà kí wọ́n má bàa mọ̀ pé ìyàwó Jèróbóámù ni ọ́, kí o sì lọ sí Ṣílò. Wò ó! Wòlíì Áhíjà wà níbẹ̀. Òun ni ó sọ nípa mi pé màá di ọba lórí àwọn èèyàn yìí.+ 3 Mú búrẹ́dì mẹ́wàá dání àti kéèkì tí a bu nǹkan wọ́n àti ṣágo* oyin, kí o sì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó máa sọ ohun tí á ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”
-