34 Àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì yóò fòróró yàn án+ níbẹ̀ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì; lẹ́yìn náà kí ẹ fun ìwo, kí ẹ sì sọ pé, ‘Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o!’+
39 Ni àlùfáà Sádókù bá mú ìwo òróró+ láti inú àgọ́,+ ó sì fòróró yan Sólómọ́nì,+ wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fun ìwo, gbogbo èèyàn náà sì ń kígbe pé: “Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o!”