-
1 Àwọn Ọba 12:28-30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Lẹ́yìn tí ọba gba ìmọ̀ràn, ó ṣe ère ọmọ màlúù wúrà méjì,+ ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Wàhálà yìí ti pọ̀ jù fún yín láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé, ìwọ Ísírẹ́lì, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 29 Ìgbà náà ni ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì gbé ìkejì sí Dánì.+ 30 Nǹkan yìí mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀,+ àwọn èèyàn náà sì lọ títí dé Dánì kí wọ́n lè jọ́sìn èyí tó wà níbẹ̀.
-
-
Hósíà 8:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Torí láti Ísírẹ́lì ni èyí ti wá.
Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe ni, kì í ṣe Ọlọ́run;
Ọmọ màlúù Samáríà yóò di èérún.
-