12 Hásáẹ́lì béèrè pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń sunkún?” Ó fèsì pé: “Nítorí mo mọ jàǹbá tí o máa ṣe fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.+ Wàá sọ iná sí àwọn ibi olódi wọn, wàá fi idà pa àwọn ààyò ọkùnrin wọn, wàá fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wàá sì la inú àwọn aboyún wọn.”+