4 Nígbà tó yá, Jèhóáhásì bẹ Jèhófà fún ojú rere, Jèhófà sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ torí pé ó ti rí ìnira tí ọba Síríà mú bá Ísírẹ́lì.+ 5 Jèhófà wá fún Ísírẹ́lì ní olùgbàlà+ kan tó máa gbà wọ́n lọ́wọ́ Síríà, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa gbé nínú ilé wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.