26 Nítorí náà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi èrò kan sọ́kàn Púlì ọba Ásíríà+ (ìyẹn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà), tí ó fi kó àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè lọ sí ìgbèkùn, ó kó wọn wá sí Hálà, Hábórì, Hárà àti odò Gósánì,+ ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.