19 Torí náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì rí Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì níbi tó ti ń fi àwọn akọ màlúù tí wọ́n dì ní méjì-méjì sọ́nà méjìlá (12) túlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì wà pẹ̀lú ìkejìlá. Nítorí náà, Èlíjà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ju ẹ̀wù oyè rẹ̀+ sí i lọ́rùn.
21 Nítorí náà, ó pa dà lọ, ó mú akọ màlúù méjì, ó pa wọ́n,* ó sì fi ọ̀pá ohun èlò ìtúlẹ̀ náà se ẹran wọn, ó fún àwọn èèyàn náà, wọ́n sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó gbéra, ó tẹ̀ lé Èlíjà, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+