-
2 Kíróníkà 32:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Ohun tí Senakérúbù ọba Ásíríà sọ nìyí, ‘Kí lẹ gbẹ́kẹ̀ lé tí ẹ fi dúró sí Jerúsálẹ́mù nígbà tí a dó tì í?+
-
-
Àìsáyà 36:4-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 5 Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 6 Wò ó! Ṣé Íjíbítì tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e.+ 7 Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 8 Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà+ pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n. 9 Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 10 Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ilẹ̀ yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’”
-