21 Àmọ́ wọ́n dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 22 Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé àti Ṣébínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.