22 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe;+ Ámọ́nì rúbọ sí gbogbo àwọn ère gbígbẹ́ tí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe,+ ó sì ń sìn wọ́n. 23 Àmọ́ kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà+ bí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;+ kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ámọ́nì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.