-
Jẹ́nẹ́sísì 19:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àwọn áńgẹ́lì méjì náà dé Sódómù ní alẹ́, Lọ́ọ̀tì sì jókòó sí ẹnubodè Sódómù. Nígbà tí Lọ́ọ̀tì rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀.+ 2 Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ̀yin olúwa mi, ẹ jọ̀ọ́ ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín, kí ẹ sùn mọ́jú, ká sì fọ ẹsẹ̀ yín. Ẹ lè dìde ní ìdájí, kí ẹ sì máa lọ.” Wọ́n fèsì pé: “Rárá, ojúde ìlú la máa sùn mọ́jú.” 3 Àmọ́ kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀, títí wọ́n fi tẹ̀ lé e lọ sílé rẹ̀. Ó se àsè fún wọn, ó yan búrẹ́dì aláìwú, wọ́n sì jẹun.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 13:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Mánóà sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́, dúró, jẹ́ ká se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.”+
-