-
Jeremáyà 36:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Ọba jókòó nínú ilé ìgbà òtútù, ní oṣù kẹsàn-án,* iná sì ń jó nínú àdògán iwájú rẹ̀. 23 Lẹ́yìn tí Jéhúdì bá ti ka abala mẹ́ta tàbí mẹ́rin, ọba á fi ọ̀bẹ akọ̀wé gé apá ibẹ̀ dà nù, á sì sọ ọ́ sínú iná tó ń jó nínú àdògán náà, ó ṣe bẹ́ẹ̀ títí tó fi sọ gbogbo àkájọ ìwé náà sínú iná àdògán. 24 Ẹ̀rù ò bà wọ́n rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí kò fa ẹ̀wù wọn ya.
-