8Èlíṣà sọ fún ìyá ọmọ tí ó jí dìde* pé:+ “Gbéra, ìwọ àti agbo ilé rẹ, kí o lọ máa gbé ní ilẹ̀ èyíkéyìí tí o bá rí, kí o sì di àjèjì níbẹ̀, nítorí Jèhófà ti kéde ìyàn,+ ọdún méje ni ìyàn yóò sì fi mú ní ilẹ̀ yìí.”
5 Bó ṣe ń ròyìn fún ọba nípa bó ṣe jí ẹni tó kú dìde,+ obìnrin tí Èlíṣà jí ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ́dọ̀ ọba, ó wá bẹ̀ ẹ́ nítorí ilé rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀.+ Lójú ẹsẹ̀, Géhásì sọ pé: “Olúwa mi ọba, obìnrin náà nìyí, ọmọ rẹ̀ tí Èlíṣà jí dìde sì nìyí.”