-
1 Sámúẹ́lì 9:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan wà tó ń jẹ́ Kíṣì,+ ọmọ Ábíélì, ọmọ Sérórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà, ọmọ ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ó ní ọrọ̀ gan-an. 2 Ó ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù,+ ọ̀dọ́ ni, ó sì rẹwà, kò sí ọkùnrin kankan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rẹwà tó o; tí ó bá dúró, kò sí ẹnì kankan lára àwọn èèyàn náà tó ga dé èjìká rẹ̀.
-