-
Léfítíkù 23:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ní ọjọ́ tí ẹ bá wá fi ìtí náà, kí ẹ fi ọmọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rúbọ, kí ẹ fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà. 13 Ọrẹ ọkà rẹ̀ máa jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tí wọ́n pò mọ́ òróró, kí ẹ fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó máa mú òórùn dídùn* jáde. Ọrẹ ohun mímu rẹ̀ máa jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.*
-